Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjì Lílé Kọlù Orílẹ̀-èdè Japan

0 78

Ìjì líle (Typhoon Nanmadol) tí pa o kéré jù ènìyàn méjì tí àwọn 90 mìíràn sí fí àràpà yọmọ yọmọ ni guusu erékùṣù (Southern Island) tí Kyushu.

Àwọn onímọ̀ sáyẹnsì bí ojú ọjọ ṣe rí ní ìlú Japan tí kilọ nípa “Ẹrẹkẹ ati Omi Yalé” bí ọkàn nínú àwọn ìjì nlá jùlọ ṣé kọlù orílẹ-èdè náà ní ọdún diẹ sẹyìn.

Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹsan ní a tí sọ fún láti jáde kúrò ní ibùgbé wọn tí a sì tí pa iná ìjọba ní Ilé Ọ̀kẹ́ Méèédọ́gbọ̀n (350,000).

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì tí náà sọ àsọtẹlẹ pé ìjì lílé tí oju ọjọ yóò ṣe òkùnfà òun ti a mọ sí “La Niña.”

Adari Ìgbìmọ̀ Ìjọba (Prime Minister) Fumio Kishida ṣé ìdádúró ìrin àjò rẹ lọ sí ìlú New York, níbití o yẹ kí o tí sọrọ ní bí Àpéjọ Gbogbogbò tí United Nations (UN), títí di ọjọ́ Ìṣẹgun, láti ṣé amojuto ọsẹ tí ìjì náà ṣé.

Àsọtẹlẹ ìjì náà tún sọpe yóò ṣẹri pàdà lọ sí ila-oorun tí yóò kọjá ní erékùṣù Japan tí Honshu ṣáájú kí o tó lọ sí okùn ní Ọjọ́rú.

Ìyípadà ojú ọjọ náà ni yóò ṣe àkóbá fún àwọn omi òkun bíi Atlántíkì àti Karembia tí o ṣeéṣe kó tún nípa
lórí lílọ àti bibọ àwọn ìjì lílé náà.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.