Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ọlọ́pàá Tí Àwọn Olórí Ẹgbẹ́ Kàn Ní Orílẹ̀-èdè Tùnísíà Mọ́ Lè

0 80

Àwọn Olùdarí méjì tí ẹgbẹ́ alatako ní orílè-èdè Tùnísíà, Ennahdha tí wá ní atimọlé nípasẹ àwọn Ọlọ́pàá tó n rí sí ìpaníyàn.

Olórí ẹgbẹ́ náà, Rached Ghannouchi, àti ọkàn nínú àwọn aṣojú rẹ̀ Ali Laarayedh ní wọ́n fí ẹsùn kàn pé wọ́n fí àwọn onijagidijagan (jihadist) ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Síríà (Syria) ati Iraaki (Iraq).

Agbẹjọro kàn sọ pé Ọgbẹni Larayedh, tí o tún jẹ́ àgbà nínú ẹgbẹ́ alatako Islamist Ennahda, ní wọ́n tí n fí ọrọ wà lẹnu wò fún àìmọye wákàtí. Ti wọn yóò máa fi ọrọ wa Olùdarí ẹgbẹ alatako Rached Ghannouchi lẹnu wò to bá to àsìkò.

Nínú àlàyé kàn, Ennahda tá ko èyí bíí ilodi sí ẹtọ ọmọnìyàn to sí kọ́ àwọn ẹsùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Agbẹnusọ tí ẹgbẹ́ Ennahdha, Imed Khemiri, sọ pé “eyi jẹ́ ìṣẹlẹ̀ tuntun tí inúnibíni tó sí lòdì sí òfin nitoripe àwọn lòdì sí ifipagbajọba èyítí ni wọ́n gbekalẹ lati pa awọn ènìyàn lẹnu mọ̀ àti láti bá àwọn lórúkọ jẹ́.

Àwọn ènìyàn àti àwọn olóṣèlú kàn bú ẹnu àtẹ lù Ennahdha pé o ṣé iranwọ fún alakakiti láti ẹyìn ogún tó wáyé ní ọdún 2011.

Ẹgbẹ náà ló n darí ìlú títí di àkókò kí Alakoso Kais Saied tó gbà ìjọba ní ọdún to kọjá.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.