Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ẹgbẹ́ Kàn Ṣé Idanilẹkọ Ìṣòwò Adìẹ Ní Ìgbàlóde Fún Àwọn Obìnrin Àti Ọdọ

0 182

Ilé-iṣẹ́ Quarantine Agricultural Nigeria (NAQS) tí ṣé idanilẹkọ fún àádọta àwọn olùgbé Ajerọmi/Ajegunle Federal Constituency, ní Ìpínlè Èkó, lórí ìṣòwò adìẹ ní ìgbàlódé.

Idanilẹkọ ọlọjọ marun-un náà ló wáyé ní gbọ̀ngán Bọla Ahmed Tinubu, ní Amukoko, fún àwọn Ọdọ àti Obìnrin káàkiri agbègbè náà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlú Lyrics Consulting Limited, làti gbé ìgbésí ayé àwọn aráàlú ga.

Àwọn olukopa ní bí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà kọ nípa oríṣiríṣi ìṣòwò adìẹ lọnà ìgbàlódé ti aladaani gẹgẹbi sisin adìẹ, ìbòjú to, ìdáàbòbò àti àpá àrùn, titaa rẹ̀ lọnà ìgbàlódé ní orí àyè-lù-jara.

Olórí pátápátá ti NAQS, Dókítà Vincent Isegbe, ti Olórí Quarantine, ṣé ojú rẹ̀ ACQ Ebele Uzoma, rọ àwọn olukopa làti lo ìmọ tí wọ́n kọ naa dáradára, o sọ pé ko sí iyemeji yóò ní ipá réré ní ìgbésí ayé wọ́n.

Nínú ọrọ onigbọwọ ètò náà, ẹní tó jẹ́ ọmọ ile igbimọ aṣòfin tó n ṣoju ẹkùn ìdìbò Ajerọmi/Ajegunle Federal Constituency, Taiwo Musibau, rọ àwọn olukopa làti ló ọgbọ̀n àti òye tí wọ́n gbà l’akoko ikẹkọ kí wọ́n sì kó ipá pàtàkì lórí ètò ẹka ọgbin tí orílẹ̀-èdè yíì.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.