Take a fresh look at your lifestyle.

Algeria Vs Nigeria: Dennis Yóò Rọ́pò Onyekuru Tó Fí Àràpà Ní Àbámẹ́ta

0 94

Agbàbọ́ọ̀lù Nottingham Forest, Emmanuel Dennis, ní wọ́n tí fí ìwé pé láti rọ́pò Henry Onyekuru ní ikọ́ agbàbọ́ọ̀lù Nàìjíríà fún ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹ sọrẹ pẹ̀lú ikọ́ Algeria. Ẹní tó fí àràpà ni ọjọ Àbámẹ́ta ní bí ifẹsẹwọnṣe tí ikọ́ rẹ̀ Adana Demirspor bóri ikọ́ Antalyaspor ní mẹta sí odò (3-0).

Gẹgẹ bí àtẹ̀jáde kàn látí ọdọ Àjọ Bọ́ọ̀lù afẹsẹgba Nàìjíríà (NFF) tí sọ, “a tí fí agbàbọ́ọ̀lù náà sínú ìwé akoni-mọọgba Jose Peseiro fún ifẹsẹwọnsẹ náà tí yóò wáyé ní ọjọ Ìṣẹgun, Oṣù Kẹsán Ọdún yìí.

Henry Onyekuru ní Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló di agbàbọ́ọ̀lù Kejì tí ifarapa yóò dènà làti kópa ní bí ifẹsẹwọnṣe náà lẹyìn ti agbàbọ́ọ̀lù ipò ẹyin, Leon Balogun tí Valentine Ozornwafor rọ́pò rẹ̀ ní alẹ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Super Eagles ní yóò tẹ̀dó síi Constantine fún èrè náà ní Ọjọ́ Ajé.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.