Take a fresh look at your lifestyle.

Ìwọlé Sáà Ètò Ẹ̀kọ́ 2022/2023: Ìjọba Rọ Òbí Láti Rán Àwọn Ọmọ Wọn Lọ Ilé Ẹ̀kọ́

0 95

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti koro ojú sí ìhà tí àwọn ọmọ ilé èkó kọ sí ìwọlé sáà ẹkọ míràn fún ọdún 202/2023.

Nígbà tí o n sọrọ léyìn tí o ṣe ibẹwo sí àwọn ilé ẹkọ kan ní ìlú ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ to wa ni ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí ṣe Alága Ètò Ẹkọ Kárí ayé ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Omowe Nureni Adeniran rọ àwọn òbí àti alágbàtọ láti jòwó àwọn ọmọ wọn láti máa lọ sí ilé èkó.

Ọ̀mọ̀wé Adeniran, nínú atẹjade tí o fi ṣọwọ́ sí àwọn akoroyin sàlàyé wípé òun se àbẹwò yìí láti mọ bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe gbaradi fún èkó sáà tuntun yìí. O wa rawọ ẹbẹ sí àwọn òbí ní ìgbèríko láti máṣe di àwọn ọmọ lọwọ ilé ẹkọ nítorí káràkátà ọjọ́ ọjà.

Bákan náà ni Komisana fún Ètò Ẹkọ, Sáyẹnsì ati Ìmọ̀ Ẹrọ ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Agbẹjọro Rahman Abdul-Raheem ti sọ wípé ìdá àádọta ninu ọgọrun (50%) ni gbedeke eesi ìdánwò fún akẹ́kọ̀ọ́ láti ipele kan sí òmíràn.

Komisana tún jẹ kí o dì mímọ pé akékòó onipele SS1 ati SS2 ní láti yege nínú Èdè Gèésì tabi Ìṣirò pẹlu awọn iṣẹ mẹrin míràn, eleyii ti yóò fún wọn ní anfààní ati gbà igbega sí ìpele tó kàn.

 

Abiola Olowe
Ibàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.