Take a fresh look at your lifestyle.

Pantami Gba Àmì Ẹ̀yẹ Mínísítà Tí Ó Fa Akọ Yọ

0 91

Mínísítà tí ó wà fún ètò ìbára ẹni sọ̀rọ̀ àti ọrọ̀ ajé orí ayélujára ọ̀jọ̀gbọ́n Isa Pantami ti gba àmì ẹ̀yẹ ẹni tí ó se dáadáa jùlọ lórí ọrọ̀ ajé orí ayélujára.

 

Ètò náà wáyé láti fi mọ rírì isẹ́ ribiribi tí ó se  lórí ọrọ̀ ajé àti ìwé ìdánimọ̀ ọmọ Nàìjíríà. Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia ni ó fi àmì ẹ̀yẹ náà dáa lọ́lá.

 

Ayẹyẹ yìí jẹ́ ìfikẹ́gbẹ́  àmì ẹ̀yẹ ọjọ́ ìdára ẹni mọ̀ ti àgbáyé ti ọdún 2022, tí ìpínlẹ̀ Abia se àgbékalẹ̀ rẹ̀.

 

Mínísítà sì gba ìjọba ìpínlẹ̀ Abia ní ìyànjú láti lo ànfààní ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé ìjọba àpapọ̀ láti fi gbé ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà lárugẹ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.