Take a fresh look at your lifestyle.

Ilẹ̀-Rúrú Pa O Kéré Tán Ènìyàn Méjìlélógún Ní Nepal

0 60
Látàrí Òjó àrọtúnrọ tí ó rọ ní Ìwọ-Oòrùn Nepal, Ilẹ̀-Rúrú gba ẹ̀mí ènìyàn méjìlélógún, nígbà tí àwọn mẹ́wàá sì Fárápa.

 

Àwọn ìkọ Ádólà Ẹ̀mí sá gbogbo ipá wọ́n láti kó àwọn tí Ilẹ̀-Rúrú tí sìn láyé kúrò.  Agbẹnusọ àwọn Ọlọ́pàá, Dan Bahadur Karki, sọ pe ní Agbegbe Achham,  Kathmandu ni ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ibí yìí tí ṣẹlẹ̀.

 

Ìròyìn fi tó wà létí wí pé Àwọn tí wọ́n yàndá ará wọn, Ọlọ́pàá àti àwọn Ológun tí wọn ń dólà-ẹ̀mí ní wọ́n kún bẹ ni pète mú, tí wọ́n ń wá àwọn to sọnù ni Achham.  Àwọn Aláṣẹ rí òkú Apẹja kan ni Àgbègbè Kailali tí àgbàrá omi Òjó gbé lọ si Odo Geta.

 

Síwájú sí, Omiyále àti Ilẹ̀-Rúrú jẹ́ ìjàńbá tí ó wọpọ láàárín Oṣù kẹfa sì ìkẹsàn ni agbgbe orí òkè ní Orílẹ-èdè Himalayan
Gẹgẹ bi àkọsílẹ̀ ìjọba, nínú ọdún yìí nìkan ó kéré tán àádọ́rin ènìyàn ni ó tí jẹ Ọlọ́run nipe, tí àwọn mẹ́tàlá sì tì di ẹni-ànùn látàría Omiyále àti Ilẹ̀-Rúrú.

 

Yagya Raj Joshi, Oṣiṣẹ ni Kailali sọ pé àwọn bi Ẹẹdẹgbẹ̀tá le lẹ́gbẹ̀rún ènìyàn ní ó tí dì aláìníle lórí tí wọn ń sún káàkiri.
Àwọn àwòrán Oko ti Omiyále tì bàjẹ́, Afárá to ti dibàjẹ́ àti àwọn ará Abúlé tí Omi mú dáyá ni ìròyìn ti Awọn Oniròyìn ìbílẹ̀ ń gbé
Leave A Reply

Your email address will not be published.