Take a fresh look at your lifestyle.
Independence

Oǹdíje Gómìnà APC  Ní Ìpínlẹ̀ Niger Ṣèlérí Ìdá Aárùn ún dín lógójì Òkodoro Ìṣe Fún Àwọn Obìnrin

0 135

Oǹdije Gómìnà APC, ní àárín gbògbò ìpínlẹ̀ Niger, Alhaji Umaru Bago ti ṣèlérí ìdá Aárùn ún dín lógójì Òkodoro Ìṣe ti United Nation’s, (UN) fún àwọn Obìnrin tí wọ́n bá yàn òun sí ipò.

Ondije náà sọ èyí nígbà tí o gbàlejò  àwọn Convener and National Coordinator of Progressive Ambassadors for Tinubu/Shettima 2023, (PATS4BATS 2023), Hajiya Aisha Halilu.

Hajiya Aisha Halilu sọ wípé òun darí àwọn ikọ̀ náà wá láti fi ifara wọn mọ Bago fún iṣẹ ríbiribi to ti ṣe fún àwọn ènìyàn pàápàá jù fún àwọn obìrin ni ipinle naa.

Ó fi kun pé, ikọ̀ òun yóò túbọ múra sí akitiyan wọn láti ríi wípé òǹdíje Gómìnà àti Ààrẹ lábẹ́ òṣèlú APC ni ó já ewé olúborí ní ìpínlè náà.

Awọn ẹgbẹ náà wá Yàn  gégébí Asíwájú ẹgbẹ́ PATS4BATS 2023, òun náà wá sọ wípé òun kòní já àwọn obìnrin kulẹ̀ nínú akitiyan wọn.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.