Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọ Àgùdà Sayeye Àádọ̀ta Ọdún Ìrántí Bísọ̀ọ̀bu Áfíríkà Àgbà Àkọ́kọ́ Tí Ìlú Èkó

0 68

 

Àwọn Àlùfáà ìjọ àgùdà péjopọ̀ ní ìlú Èkó láti sayeye Àádọ̀ta Ọdún Ìrántí Bísọ̀ọ̀bu Áfíríkà Àgbà Àkọ́kọ́ tí Ìlú Èkó, eni ọ̀wọ̀ John Aggey.

Níbi ayẹyẹ ọ̀hun, Episcopal Archbishop ti Ìlú Èkó, Pásítọ̀, Monsignor Bernard Okodua rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn krístì láti tẹ̀lé àwòkọ́ṣe ìwà ìrẹ̀lẹ̀ krístì nípa ṣíṣe ìgbọràn sí ìfẹ Ọlọ́rùn nigbagbogbo.

O ṣàpèjúwe Bísọ̀ọ̀bu Àgbà Aggey tó gbé àwọn àlùfáà kékèké gẹ́gẹ́bi ẹni jẹ́jẹ́,  onírẹ̀lẹ̀ eniyan Ọlọ́run tó se dáadáa sí àwọn ènìyàn nnkan bi odun meje to lo bi bísọ̀ọ̀bu àgbà, ó gba àwọn àlùfáà yóku láti tọ ìsísẹ̀ rẹ̀.

Àlùfáà naa rọ àwọn adari ẹ̀ṣìn ni orílè-èdè Nàìjíríà láti lo ipò wọn láti rí wípé àlàáfíà òun ìrẹ́pọ̀ jọba làárín àwọn ènìyàn àti ní orílẹ̀-èdè yìí. Ó tún gba àwọn adari òṣèlú láti rí wípé kòsí wàhálà ẹ̀sìn ati ẹlẹ́yà kò mẹ̀yà láwùjọ.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.