Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì Ààrẹ Ọ̀sínbàjò Yóò Sójú Orílẹ̀ Èdè Yìí Níbi Ètò Ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth Il Ní Ìlú London

0 40

Igbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò yóò Soju Orilẹ Ede yii nibi orisii alake eto ni ojo Aiku àti ọjọ Aje fún Isinku Obabinrin Elizabeth Il ni United Kingdom.

Igbakeji Aare, Ojogbon, Ọ̀sínbàjò yóò padà sórílẹ̀ èdè ní ẹ̀yìn ètò ìsìnkú.
Gbogbo eléyìí di mímọ̀ láti ọ̀dọ̀ agbenusọ Igbákejì Ààrẹ, Laolu Akande ní ọjó Àbámẹ̀ta.

Ọ̀jògbón Ọ̀sínbàjò yóò Kúrò ní Àbújá láti lọ darapọ̀ mọ́ ìdílé ọba, àwọn olórí lágbayé bíi, ara àwọn commonwealth, olórí orílè-èdè, Olórí àwọn Gómìnà, Ààrẹ, Prime Ministers, ìdílé àwọn ọba látòkè òkun níbi ayẹyẹ náà ti yóò wáyé ni Westminister Abbey ní ọjó Ajé.

Obabinrin Elizabeth Il jẹ́ olórí Commonwealth àti ọbabìnrin tó jẹ tí ọjó rẹ gùn jù nígbà ayé rẹ̀.
Ó jáde láyé ní ọmọ ọdún mẹ́rìn dín lọ́gọ́rù ún ní ọjó kẹjọ oṣù kẹ́sàn án ọdún yìí ní Balmoral Castle, Scotland.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.