Take a fresh look at your lifestyle.

Àárẹ̀ Nàìjíríà Ṣe ìlérí Láti Tẹ Síwájú Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Lórí Àwọn Ìbéèrè Àjọ Olukọni Ìlé-ẹkó Gíga

0 83

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ṣé ìlérí láti ṣé ìtẹ̀síwájú lórí ìfọrọwanilẹnuwo pẹ̀lú àwọn tó níí ṣé ní étò ẹ̀kọ́, làti wà òpin sí rògbòdìyàn ẹgbẹ àwọn olukọni ilé-ẹ̀kọ́ gíga, Academic Staff Union of Universities (ASUU).


O ṣé ìlérí náà ní Ọjọ́ Ẹtì lẹ́yìn ìpàdé tó se pẹ̀lú Alaga ati awọn èékàn ní ẹka ètò ilé-ẹ̀kọ́ gígajùlọ tí ìjọba àpapọ̀, èyí tó wáyé ní Abùjá, Olú-ìlú orílẹ-èdè náà.

Ojogbon Nimi Briggs to lewaju awọn akẹgbẹ rẹ̀ níbí ìpàdé náà sọ nínú ọrọ rẹ pé; àwọn n ri Ààrẹ gẹgẹ bí alákóso àgbà orílẹ̀-èdè yìí, baba fún gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olubẹwo sí gbogbo ilé-ìwé gíga tí ìjọba àpapọ̀.


O fí kún pé pẹlú gbogbo rògbòdìyàn Idasẹsilẹ awọn olukọni ilé-ìwé gíga láti oṣù méje sẹyìn, “Ọlá iwájú ètò ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní orílẹ̀-èdè náà sí dára,” o ṣe apejuwe bi ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí Ìbàdàn (University of Ibadan) tí ṣé wà lára àwọn ile-ẹkọ to dara jù ni àgbáyé.
Ọjọgbọn Briggs yìn Ìjọ̀ba apapọ fún àwọn ipá tí wọ́n tí sá àti àdéhùn tí wọ́n ṣé làti jẹ ki iyansẹlodi náà di òun ìtàn bi wọ́n ṣé jẹ́ kí owó oṣù àwọn olukọni náà gbé pẹ́ẹ̀lì sí. Sibẹsibẹ, òun n béèrè fún alekun owo síi, ní ìwòyè sí ètò ọrọ-aje tí orílẹ-èdè náà.
O tẹ síwájú nínú ọrọ rẹ pé kí ìjọba ṣe àtúnyẹwò òfin “ko s’iṣẹ, ko s’ówó (No-work, No-pay).” O sí ṣe ìlérí pé àwọn olukọni yóò ṣe àtúnṣe fún àkókò tó pàdánù l’akoko iyansẹlodi náà ní kété tí ọtún ba ti gbọ́ òsì yèé.

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Goodluck Nana Opiah, sọ pé gbogbo ìgbìyànjú ati ìlà kàkà Ìjọ̀ba Nàìjíríà ni bí iyansẹlodi náà yóò ṣe di òun igbagbe ṣùgbọ́n, àáké ní àjọ akẹkọ ASUU fí kọ orí tí wọ́n sì dúró ṣinṣin.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.