Take a fresh look at your lifestyle.

Porte, Agun-Kẹ̀kẹ́ Ọmọ Orílẹ̀-èdè Australia Fẹ̀yìntì

0 67

Richie Porte ọmọ orílẹ̀-èdè Australia ti fẹyìntì Kẹkẹ gígùn, tó fi ori iṣẹ takuntakun rẹ ti bi oṣe bori Paris-Nice ati Tour Down Under lẹẹmeji nínú Ìrìn-àjò kẹkẹ gígùn.

Ẹní ọdún mẹtadinlogoji, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ineos Grenadiers jẹ́ ọmọ ọdún Mẹrinlelogun nígbàtí o tí bẹrẹ síi gun kẹkẹ, sọ lori ẹrọ ayé-lù-jara.

“mi o lérò rárá pé mo lè dé ibí tí mo de yìí nígbàtí mo bẹrẹ kẹkẹ gígùn ni Tasmania wípé Emi yóò ní àṣeyọrí báyìí ti mò sí lọ káàkiri àgbáyé, tí mo sì pàdé ọpọlọpọ awọn eniyan jankan-jankan.

“Mo ti ṣetán láti gbádùn ifẹyinti mi ṣugbọn òun ti mò gbádùn ni èré kẹkẹ gígùn”

Awọn aseyori míràn tí Porte ní, ipò kẹta lẹyin ẹni tó borí nibi ìdíje Tour de France ni ọdun meji sẹyìn, Tadej Pogacar.

O tún borí ìdíje Tour de Romandie, Tour de Suisse ati Criterium du Dauphine, láàrin àwọn mìíràn, ṣùgbọ́n àìsàn àti àwọn ìpalára ṣé idiwọ fún lọpọ ìgbà.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.