Take a fresh look at your lifestyle.

Òpópó-nà Akobo Ojurin Sí Bárékè Odogbo Yóò Mú Ìrọ̀rùn Dé Bá Ìgbòkègbodò Ọkọ̀ Ará Ìlú.

0 78

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde pẹlu Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Kayode Fayemi ti o jẹ alejo pàtàkì ti ṣí òpópó-nà oníbejì Akobo Ojurin si Bárékè Odogbo àti Afárá Abeyefo agbègbè General gas ni ìlú ìbàdàn, ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lásìkò tó n sí òpópó-nà náà jẹ kí o di mímọ̀ wípé àwọn ènìyàn agbegbe ìjọba ìbílẹ̀ Lagelu nìkan ko ni ònà náà yóò wúlò fún sùgbón àwon èèyàn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Akinyẹle, Ariwa Ìbàdàn àti ìjọba ìbílẹ̀ Ìlà oòrùn Àríwá Ìbàdàn. Bákan náà ni ònà náà yóò mú kí igbokegbodo ọkọ àti ọrọ ajé di irọrun fún gbogbo olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ mererin ohun.

Bákan náà ni gómìnà Makinde fi àsìkò náà dúpẹ́ lọwọ gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti Kayode Fayemi fún bí o ṣe wa darapo mọ ọ lati sí òpópó-nà náà.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Lagelu, Gbadamosi Kazeem náà lu gómìnà ìpínlẹ̀ Òyó l’ogo ẹnu fún síso òpópó-nà Akobo Ojurin di onibeji nítorí pé òpópó-nà yìí ló so ìlú ìbàdàn pẹlu ìpínlè Osun ati Kwara. O wa rọ gómìnà láti tẹ síwájú láti ṣe àtúnṣe àwọn ònà míràn tí wọ́n nilo àtúnṣe ni àárín ìlú.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.