Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà ṣe ayẹyẹ Ìdìbò Igali sí Àjọ Ijakadi Àgbáyé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 96

Mínísítà fún ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Sunday Dáre, ti kí Daniel Igali, Ààrẹ ẹgbẹ́ oníjàkadì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ìdìbò rẹ̀ sí Àjọ àpapọ̀ àwọn oníjàkadì àgbáyé.

Igali  gba iye ibo ti o pọ julọ,mẹtale-lọgọrin,ti o si jawe olubori laarin awọn oludije mẹtadin-logun toku, pẹlu awọn oludije mẹrin ti o ti wa nibẹ tẹlẹ ti wọn tun fẹ pada, ti wọn jọ n jijadu fun awọn ipo mẹfa ti o wa ninu ajọ naa waye ni Belgrade, Serbia.

Minisita naa rọ Igali lati lo ipo tuntun rẹ ninu ajọ onijakadi olokiki agbaye naa lati ṣe idagbasoke ere idaraya siwaju sii ni Naijiria ati Afirika.

Naijiria gba ami-eye fadaka ninu Ijakadi ni Olimpiiki Tokyo ọdun 2020 pẹlu goolu mẹta, fadaka meji ati idẹ kan ninu Awọn ere idaraya Agbaye 2022.

Leave A Reply

Your email address will not be published.