Ìdaṣẹ́sílẹ̀: Ààrẹ Nàìjíríà Ṣe ìlérí Láti Ṣe Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Lórí Àwọn ìbéérè Àwọn olùkọ́ni
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí ti ṣe ìlérí láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò síwájú síi pẹ̀lú àwọn tí ó níí ṣe, lórí àti fi òpin sí ìdasésílẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ẹ tí àwọn olùkọ́ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga, lábẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn olùkọ́ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga fáfítì, (ASUU).
O ṣe ileri naa ni Ọjọ Ẹti lẹyin ipade pẹlu Alaga ati awọn ọmọ ẹgbẹ adari awọn ile-iwe giga ijọba apapọ, ni Ile-igbimọ Ipinlẹ, ni Abuja, olu-ilu orilẹ-ede.
Aarẹ wa sọ pe oun o ni pada sẹyin lori eto imulo to ti wa nilẹ tẹlẹ, “Emi yoo ṣe awọn ijumọsọrọ siwaju, ati pe Emi yoo si pada wa fun yin lesi.”
Ojogbon Nimi Briggs,ti o dari ipade awọn adari ile-ẹkọ giga ọhun sọ pe, awọn wa lati ṣe ipade pẹlu Aarẹ ni ipele agbara mẹta to ni; “Gẹgẹ bi Aarẹ ati Alaṣẹ Agba, gẹgẹ bi baba orilẹ-ede, ati bi Alejo si awọn ile-ẹkọ giga fafiti apapọ.”
Leave a Reply