Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpini sí Isọri TotalEnergies CHAN yóò wáyé ní Orílẹ̀-èdè Algeria Ní Oṣù Kẹwàá.

0 85

Àjọ àgbàbọ́ọ̀lu afẹsẹgba Áfíríkà (CAF) tí fí ìdí rẹ̀ mulẹ pé ìpini sí Isọri ti TotalEnergies African Nations Championship Algeria 2022 (CHAN) yóò wáyé ní ọjọ́ kínní Oṣu Kẹwàá, ọdún 2022.
Ipini sí ìsòrí náà yóò ní Algiers, olú-ìlú Algeria. ìdíje náà ni yóò waye laarin ọjọ́ Kẹtala Oṣù Kini sí ọjọ Kẹrin Oṣu Kejì ọdún 2023.

Àwọn orílẹ-èdè méjìdínlógún pẹ̀lú Algeria tí yóò gbà àlejò ní yóò díje nínú ìdíje náà lẹhin ipinnu CAF lati mu oyè orílẹ-èdè ti yóò kópa nínú ìdíje náà pọ̀ sí.

Orílẹ-èdè mẹjọ ló kópa ni ọdun 2009, tí o si di mẹrindinlogun ni ọdun 2011 tó wáyé ní Sudan ni bayi o ti di méjìdínlógún.

Àwọn orílẹ-èdè to peregede jẹ:

Algeria (olugbalejo), Morocco (Olubori 2018, 2020), Libya (Olubori 2014), Senegal (ipo kerin 2009), Mali (ipò Kejì ni 2016, 2020), Mauritania (ìkópa ẹlẹẹkẹta), Côte d’Ivoire (Ipo kẹta ni 2016), Niger (ikopa ẹlẹẹkẹrin), Ghana (ipò Kejì ni 2009, 2014), Cameroon (ipo kẹrin ni ọdun 2020), Congo (ìkópa ẹlẹẹkẹrin), DR Congo (Olubori ni 2009, 2016), Uganda (ìkópa ẹlẹẹkẹfa), Sudan (ipo kẹta ni 2011, 2018), Ethiopia (ìkópa ẹlẹẹkẹta), Mozambique (ìkópa ẹlẹẹkeji), Angola (ipò Kejì ni 2011), Madagascar (ikopa alakọkọ).

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.