Take a fresh look at your lifestyle.

Tinubu Ní Okun Àti Agbára Láti Díje Fún Ipò Ààrẹ-Agbẹnusọ Olùpolongo Ìbò

0 74

Olùdije Ààrẹ ẹgbẹ́ òsèlú APC, Ọ́gbẹ́ni Bọla Tinubu jẹ ẹni ti ara rẹ le koko to si ya gaga fun ibo aarẹ to n bọ. Agbẹnusọ ti Tinubu Campaign Organisation, Ọgbeni Festus Keyamo lo sọ eyi. O fi kun pe Ogbẹni Tinubu kò setán láti juwọ́ sílẹ̀ ninu ikopa rẹ gẹgẹ bí oludije ipo aarẹ bi awọn eniyan kan se n gbe poyi ẹnu lori ẹrọ ayelujara.

Síwájú síi, o sọ wipe kosi otitọ ninu Fánrán ti wọn gbe kiri lati inu ẹgbẹ oselu Labour ti Ọgbẹni Peter Obi láti fi tàbùkù báa. O sọ wipe, Ọgbẹni Peter Obi fẹ lo ọgbọn àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni lati gbe ara rẹ kalẹ fun orilẹ ede Nàìjíríà gẹ́gẹ́bí oludije to dára jù ni.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.