Take a fresh look at your lifestyle.

Olóyè Pàtàkì Nínú Ẹgbẹ́ Òsèlú PDP Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Òsèlú APC Ní Ìpínlẹ̀ Kebbi

0 81

 

Olóyè pàtàkì ninu ẹgbe oselu PDP ni agbegbe ijoba Ibile Danko/Wasagu ni ipinle Kebbi, Alhaji Jinaidu Wasagu ti lo darapo mo egbe oselu APC.

Àwọn alága àtijoọ́ mẹ́jọ ninu wọ́ọ̀dù PDP, awon akowe, ọdọ ati awon adari Lobinrin ni won wa lara awon to pelu Ogbẹni Wasagu lati dara pọ mọ ẹgbẹ APC nibi ayẹyẹ kan ni ọjọ aje ni Ìpínlẹ̀ Kebbi.

Nígbà tó n kí wọn kaabọ sínú ẹgbẹ́, alaga gbogbogbo ti Ìpínlẹ̀ naa, Alhaji Abubakar Kana ki won káàbọ̀, o si ki wọn ku orire pe ipadabo Ọgbẹni Wasagu yoo so eso rere fun ipinlẹ naa.

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ fun wọn pe gbogbo mùndùnmúndùn to n bẹ ninu ẹgbẹ naa ni wọn o jẹ gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ tuntun otitọ.

Wasagu sọpé iwa aise idajọ ododo ati ìwà ìmọtaraẹni nìkan ninu ẹgbẹ PDP lo jẹ ki awọn  darapọ mọ ẹgbẹ APC.

Ó sì fi dáwọn lójú pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ alátileyin òun ni  ó ń bọ̀ wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC láti ìbílẹ̀ Danko/Wasangu ati Zuru Emirate.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.