Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Ìjọba Ológun Ti Orílẹ̀ Èdè Burkinafaso Yọ Mínísítà Dànù

0 106

 

Olórí Ìjọba Ológun ti orílẹ̀ èd̀e Burkinafaso, Colonel Paul Henri Damiba ti yọ Mínísítà ètò ààbò rẹ̀ dànù bíi ẹni yọ jìgá.

Nínú òfin gbèǹdéke méjì tí ó kà lórí ẹ̀rọ móhùn-máwòrán ti orílẹ̀ èdè náà ló ti yọọ Ọ̀gágun Barthelemy Simpore náà dànù. Ó sọ pé àyè ipò rẹ̀ tó sófo di tòun.

Ìdí tí ó fi tún ìjọba tò kò sé lálàyé nínú íkéde rẹ̀.

Colonel Damiba gba ìjọba ní osù kíní ọdun yìí tí ó fi ẹ̀sùn kan ìjọba àná pé wọn kòleè gbógun ti ìsòrò ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà; èyí tí ìsòro ti alákatakítí Ìsìláàmù ń se ara wọn.

Ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn ló ti di olóògbé nínú àwọn ìkọlù búburú náà tí nǹkan bíi Mílíọ̀nù méje ti di ìsáǹsá àti alárìnkiri.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.