Ìyanṣẹ́lódì àwọn olùkọ́ni: Àwọn ọmọ ilé-ìwé Dínà òpópónà mọ́rosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn ọmọ ilé-ìwé lábẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ilé-ìwé Nàìjíríà lápapọ̀,NANS, ti dínà òpópónà mọ́rosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn nítorí ìdaṣẹ́sílẹ̀ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ olùkọ́ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga fáfitì, ASUU rawọ́ lé.
Awọn ọmọ ile-iwe naa di ẹgbẹ opopona mejeeji naa ni ọjọ Iṣẹgun, ti eyi si fa boolọ o ya funmi,ti awọn ọkọ ko si le lọ geerege si ilu Eko ati jade bakannaa.
Alaga NANS nipinlẹ Ogun, Simeon Damilola,ti o dari ifẹhonuhan naa ṣapejuwe idaṣẹsilẹ to n lọ lọwọ gẹgẹ bi ibanujẹ ọkan, o si ke si ijọba orilẹ-ede Naijiria lati ṣe ohun to tọ to yẹ.
O ṣeleri pe awọn ọmọ ile-iwe naa yoo tẹsiwaju ifẹhonuhan wọn kaakiri awọn opopona pataki ni Guusu Iwọ-oorun titi ti Ijọba Naijiria yoo fi dahun si ibeere idaṣẹsilẹ awọn olukọni naa.
Leave a Reply