Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje Bọ́ọ̀lù Líìgì Ti Orílẹ̀ Èdè Aláwọ̀ Funfun Yóò Bẹ̀rẹ̀ Padà

0 68

 

Ìdíje bọ́ọ̀lù Líìgì ti Orílẹ̀ èdè aláwọ̀ funfun yóò bẹ̀rẹ̀ padà lẹ́yìn tí wọ́n ti kéde ìdádúró rẹ̀ tẹ́lẹ̀ látàrí ikú ọbabìnrin Elizabeth II.

Ìdíje to ye ko waye ni orile ede bii England, Wales, Scoltland ati Northern Ireland ni won sun siwaju lati bu eye ikeyin fun obabinrin ti o waja naa.

Ìdíje ere boolu agbabuta Liigi yoo bere pada ni ojo eti nígbàtí Aston Villa yoo gba Southampton lálejò t́i ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Fulham náà yóò náa tán bí owó pẹ̀lú Nothingam Forest.

Kò tíì di mimọ̀ pe gbogbo idije ni EFL ni yoo bere gege bi àlàkalẹ̀ ni òpin ọ̀sẹ̀ látàrí ìtẹ́ ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún babìnrin ti yóò wáyé ni ojo aje ati akitiyan awon ọlọ́pàá lati seto aabo.

Àwọn alakóso ere idaraya yoo se ipade pẹ̀lu ìjọba lọ́jọ́ ajé lati mọ bí eto gbogbo yoo se lo, Ajo EFA ti kede pe ere boolu pelu idije Liigi ti àwọn obìnrin ati ti ipegede FA Cup, kete ni yoo bere.

Àjo Scottish FA so wipe, erongba won ni ki ere boolu bere pada bi o se wa tele, awon oloye ninu boolu aláfesẹ̀gbá ti Welsh naa so wipe idije yoo bere pada ni ojo isegun.

Idije Liigi ti Europa laarin egbe agbaboolu Arsenal ati PSV ni ojo ojobo ni koni lee waye mo latari ohun eelo lati odo awon olopaa ti ko ni si ni akoko naa.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.