Take a fresh look at your lifestyle.

Fóllíbọ́ọ̀lù(Volleyball): Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà Borí Ìdíje Ilẹ̀ Adúláwò Tí Ọ̀dọ́ Tí Ọjọ́ Orí Wọn Kòju Ọ̀kàndínlógún Lọ.

0 110

 

Orilẹ̀ èdè Nàìjíríà ló tún gbégbá orókè nínú ìdíje Fóllíbọ́ọ̀lù ti Ilẹ̀ Adúláwò ti ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kòju Ọ̀kàndínlógún bí wọ́n se se kẹ́yìn.

Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà lu Orilẹ̀ èdè Íjíbíítì (Egypt) bí ẹni lu bàrà ní mẹ́ta sódo 3-0 (25-20,25-18,31-29) ni idije 2022 U19 Boys African Nations Volleyball Championship to sese tẹnu bepo ní Orilẹ̀ èdè Morocco ní ọjọ́ Àìkú.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá ti Orilẹ̀ èdè Nàìjíríà yin awon omo agbaboolu re fun akitiyan ati ise takuntakun ti won se lati ri wipe won gbewuro soju iko ti Orilẹ̀ èdè Íjíbíítì. O so wipe awon agbaboolu naa gbaa gegebi oun ti paa lase ki won se lati ibere idije naa titi de opin.

Ó wá fi orí ìjáwé olúborí náà sọ Ọlọ́run ọba ati gbogbo ololufe ere Fóllíbọ́ọ̀lù ni Orilẹ̀ èdè Nàìjíríà fun atileyin won.

O sọ síwájú pé, inú òun dùn pé ikọ̀ ti Nàìjíríà náà ló gba ife ẹ̀yẹ olúborí ní ọdún 2020 tí wọ́n sì tún gbàá báyìí. O wípé, ọ̀nà àwọn agbábọ́ọ̀lù náà sì jìn bótilẹ̀jẹ́wípé wọ́n borí báyìí, òun gbàgbọ́ pé ibi giga ni wọ́n ń lọ ní ọjọ́ ọ̀la.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.