Olúbàdàn ti ilẹ ìbàdàn, Oba Ọlálékan Balogun, Allí Okunade II ti ké sí ọmọ orilẹ èdè Nàìjíríà láti máṣe gbé ọrọ ẹsin tàbí ẹyà ga jù sùgbón kí wọn ni afojusun fún àwọn ètò tí yóò mú iṣọkan ati ìdàgbàsókè dé bá orílè èdè Nàìjíría.
Olúbàdàn ló sọ òrò yìí lásìkò tí oludije dù ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ Social Democratic party (SDP), Ọmọ Ọba Adewole Adebayọ pẹlu awọn eekan nínú ẹgbẹ náà ṣe abẹwo sí i ní ilé rẹ tó wà ní agbègbè Alarere ni ìlú ìbàdàn tí ì ṣe olú ìlú ipinle Òyó ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ ede Nàìjíríà ṣáájú ifilole ẹkùn ilé ẹgbẹ náà.
Oba Balogun nínú ọrọ rẹ ke sì tolori- telemu ọmọ orilẹ ede Nàìjíríà láti máṣe fi ọrọ ẹsin tàbí ẹyà ṣe sugbon ki wọn s’apa wọn láti rí daju wípé òpin dé bá ipenija eto ààbò, ìṣòro airise fún àwọn ọdọ, ati ètò orò ajé tó denu kodò.
Ṣáájú nínú ọrọ rẹ, Ọmọ Ọba Adebayọ fi aidun inu rẹ hàn sí bí àwọn ọmọ ologun se fagi le eesi idibo odun 1993 ninu eyi ti Oloogbe MKO Abiola ti jáwé olubori sugbon ti won kò jé ki àbá rẹ wá sí imusẹ. O wa so di mimọ pe oun jáde láti dije du ipo ààrẹ ni ònà àti da ògo orilẹ ede Nàìjíríà padà nípa ṣíṣe ètò ààbò, ọrọ ajé, iṣẹ ṣiṣe, iṣọkan ati fífi ẹtọ ọmọ orílè èdè Nàìjíríà fún wọn.
Bákan náà ló tun fi kun ọrọ nígbà tí o sọ wípé, ti awọn eyan ba ri wípé ìjọba tó wà lóde ṣe ohun tí ará ìlú n fẹ laifi ti ẹsin tàbí ẹya ṣe, kòní soro fún wọn láti ní ìgbàgbọ nínú irú ìṣèjọba bẹẹ.
Lara awon tó kowo rìn pèlú ọmọ ọba Adebayo ni Oludije du ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Òyó labẹ àsìá ẹgbẹ náà, Agbẹjọro Mike Lana; Oludije du ipò gómìnà ipinle Ogun, Onimọ Ẹrọ Tony Ojesina; ati oludije fún ipò ilé ìgbìmò aṣòfin àgbà tó n soju ẹkùn ìdìbò Àríwá Òyó, Honourable Mulikat Adéọlá Àkàndé.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply