Gómilnà ìpínlẹ̀ Gombe, ní Àriwá Ilà-oòrùn Nàìjíríà, Muhammad Inuwa Yahaya sọ pé olùdíje fún ipò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ̀ All Progressive Congress (APC), Aṣiwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu ní ànfàní láti jáwé olúborí ní Ariwá Ilà -Oòrùn nínú ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2023 tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.
Gomina Yahaya ti o tun jẹ Alakoso Ipolongo Tinubu ni Ariwa Ila-oorun, sọ eyi lẹyin to ṣe abẹwo si Aarẹ ologun Naijiria nigba kan ri,ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida ati Aarẹ orilẹ-ede kan ri tẹlẹ,ajagunfẹyinti Abdulsalam Abubakar ni Minna,ni ọjọ Abamẹta.
Gomina Yahaya sọ pe “Awa yoo rọwọ mu ni ariwa-ila-oorun nitootọ. A o mu ipinnu wa lati bori awọn idibo gbogbogboo ọdun 2023…si imuṣẹ.
Leave a Reply