Olórí ẹgbẹ́ ọmọ Ogún (COAS) Lieutenant General Faruk Yahaya sọ pé ọmọ Ogún Nàìjíríà lábẹ́ iṣọ rẹ̀ yóò tẹsiwaju láti fún àwùjọ padà nípa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àtìlẹ́yìn tó nípa ti awọn ara ilu n ṣé láti mú òfin ìlú dúró.
Nínú àtẹ̀jade kàn tí Olùdarí ìgbé ọrọ sí afẹ́fẹ́, Brigadier General Onyema Nwachukwu lásìkò tí wọ́n ṣí gbangan nlá kán fún àwọn ará ìlú Akinmorin ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijio ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ Jimọ ọjọ kẹsán Oṣu Kẹsán, ọdún 2022.
General Yahaya gbóríyìn fún ìdúróṣinṣin àwọn ọ̀gágun àti ọmọ-ogun tí Nàìjíríà fún iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ wọn láti dáàbò bò orílẹ̀-èdè yíì, o ní kí wọ́n dúró ṣinṣin nínú igbogunti ìpaniyàn àti ìpèníjà ààbò tí orílẹ̀-èdè náà n kojú.
Ọgagun náà sọ pé o jẹ́ apakan lára akitiyan ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí àrà ìlú àti àwọn ọmọ Ogún Nàìjíríà.
Nitoribẹẹ, o sí gbà àwọn ọmọ Ogún níyànjú láti máa ṣe ètò àlàáfíà àti iṣọkan ìlú.
Major General Olufemi Akinjobi tó jẹ́ alukoro iṣẹ́ àgbaṣe náà, to tún jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Akinmorin, sọ pé àṣeyọrí iṣẹ́ àkànṣe náà jẹ àmì pàtàkì ní ìpínlẹ̀ náà.
O ṣé àkíyèsí pé iṣẹ́ àkànṣe náà jẹ́ iṣẹ́ idasi pàtàkì tí COAS àti àlà ìlú náà bi ọdún mejilelọgbọn sẹyìn.
O sí gboriyin fún ẹgbẹ COAS fun ọlá ti wọn dá ìlú náà ati àgbègbè rẹ nípa ifọwọ́sí gbangan náà.
O ṣe ìdánilójú àtìlẹ́yìn àgbègbè àti ìrànlọ́wọ́ àrà ìlú láti jẹ́kí ìdàgbàsókè orílẹ-èdè náà tẹsiwaju.
Lekan orenuga
Leave a Reply