Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Ṣé ìwé-ẹri Ìwé-àṣẹ Fún Àwọn Oníṣòwò Ajilẹ

0 132

Ìjọba Àpapọ̀, ní Ọjọ́bọ̀, ṣé agbekalẹ àwọn iwe-ẹri àti iyọnda títà àti rírà ajilẹ ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Èyí wà nínú ọrọ kàn tí Iyaafin Modupe Olatunji, tí Federal Ministry of Agriculture and Rural development ni Abùjá

Akọ̀wé àgbà, Ernest Umakhihe, lakoko tó n pin iwe-ẹri náà sọ pé Ilé-iṣẹ́ náà tí kọ ọpọlọpọ àwọn ènìyàn tí wọ́n sì tí fí wọ̀n ránṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Mejidinlogoji ati olú-ìlú Abùjá, nipa ajilẹ, ìṣàkóso, lilo rẹ àti bi wọn ṣe fi n pa kòkòrò ọ̀gbìn.

O sọ pé àwọn oluyẹwo wọ̀nyí n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò láti lè dáàbò bò àwọn agbẹ àti àwọn ilé-iṣẹ́ ọgbin.

Umakhihe, tí Iyaafin Fausat Lawal n ṣé ojú rẹ́ tí o tún jẹ́ Olùdarí àwọn iṣẹ́ pàtàkì ní ilé-iṣẹ́ náà, sọ pé àwọn ìlé-íṣẹ́ tí kò ní ìwé-àṣẹ ko ní igbalaaye láti tá tàbí rà láti ilẹ òkèèrè tàbí ṣé ajilẹ nilẹ yíì ayaafi kì o ní ìwé-ẹri ajilẹ àti ọja-ọgbin ní orile-ede Nàìjíríà.

Umakhihe sọ pé àkókò òòrè ọfẹ oṣu meji sí ṣí sílẹ̀ fún ẹni tí kò tíì ní ìwé-àṣẹ náà kí o tó di àkókò tí wọ́n yóò máa tí àwọn ilé-iṣẹ́ tí kò ní ìwé-àṣẹ náà.

Umakhihe gbóríyìn fún Ìjọba Àpapọ̀ fún Òfin náà tí Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ́lù ní ọdún 2019.

Olùdarí, ẹ̀ka àwọn iṣẹ́ àtìlẹ́yìn àwọn ohun èlò Oko, Ọgbẹni Kwaido Sanni, sọ pé Òfin àti àwọn ìlànà koni ṣe idiwọ fún àwọn oníṣòwò ọgbin bí kìíse lati dáàbòbo àwọn oníṣòwò gidi, awọn agbẹ, àyíká àti gbogbo àrà ìlú.

Ọgbẹni Ishaku Buba tó jẹ́ Igbákejì Olùdarí àwọn ohun èlò Oko ni aṣojú Ọgbẹni Sanni.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.