Camilla ní ìyàwó, olufọkantan àti ìfẹ́ ayé Ọba Charles fún ọdún mẹ́tàdínlógún. Ní báyìí, O tí di Olórí Ọba.
Ọpọ ènìyàn ló tí mọ lára láti máa rí Camilla ní ẹgbẹ ọkọ rẹ̀ níbí ayẹyẹ àti ajọyọ orílẹ-èdè, ṣùgbọ́n o ní àwọn tí bẹrẹ, ọjọ́ tipẹ.
Fún ọpọlọpọ ọdún ní àwọn akọroyin fí dá láàmú, tí wọ́n sì tabuku rẹ̀ fún ọdún tó pọ̀. Ṣùgbọ́n o ní sùúrù, tó sí fí ìwà pẹlẹ gbà ayé rẹ̀ nínú ààfin gẹ́gẹ́ bí Obìnrin tó dàgbà jù.
Ìrìn àjò nlá ló jẹ́ fún òun kí Ọmọba Charles to fi ojú kàn òun ṣùgbọ́n lẹsẹkẹsẹ ni ifẹ oun dúró lórí ọkàn rẹ.
O gbà Ọbabinrin Elizabeth II ní àsìkò diẹ kí o tó tẹwọgba Camilla kò sí kó iyán rẹ̀ kéré ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ sẹyìn.
Olórí tuntun náà lo ṣeéṣe kó má rí itẹwọgbà láti ọdọ aráàlú ní ìbẹrẹ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí o ṣé sọ nínú ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ oníròyìn kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yíì,
“Mo má n gbìyànjú láti borí nkán ki nkán, kì n sí tẹ̀síwájú.”
Fífẹ́ arẹmọ-Ọba ní kó jẹ́ àjòjì fún Camilla Rosemary Shand, ẹni tí wọ́n bi ní ọjọ kẹtadinlogun osu Keje ọdun1947 (17/7/1947). Mọlẹbi rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn nlá, olówó, ọlọrọ̀, tí wọ́n sì mọ̀ ènìyàn nlá nlá ṣùgbọ́n wọ́n kìí ṣé ìdílé ọba.
Baba Camilla, Bruce Shan jẹ Ajagun fẹyinti, tó má n ká ìwé ìtàn fún kò tó sun lalẹ. Ìyá rẹ ní Rosalinda, tí ilé mọlẹbi wọn sì wá ní Sussex. O sí ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin àti obìnrin nínú ẹbí wọ́n.
Iyatọ wa fun bi Charles ṣe dagba, ẹni to o dáwà fún ọpọlọpọ ọdún lai rí àwọn obi rẹ̀ nítorí wọ́n má n rìn ìrin ajo káàkiri àgbáyé.
Ilé ẹkọ kàn ní orílẹ-èdè Switzerland ní Camilla tí bẹrẹ ẹkọ rẹ, ti wọn si kọ nípa ìgbé ayé àwọn ènìyàn nlá nílùú London. Ìlú mọ́ọ̀kà ní àti pé níbí ọdún púpọ̀ sẹyìn, lo pàdé oṣiṣẹ ológun kàn Andrew Parker Bowles ti ibaṣepọ wọn kò sí dàn mọran.
Ṣáájú ọdún 1970, o pàdé Ọmọ-ọba Charles. Gẹgẹ bí akọwe ìtàn Ọmọ-ọba, Jonathan Dimbleby ṣe sọ, “O ní ọyaya, ni ọmọ-ọba fi fẹ́ràn rẹ̀ ní kété tó fí ojú kan-án.”
Ṣùgbọ́n Charles ṣí wà ní bíi ọmọ Ogún ọdún nígbà náà ní àkókò tó n ṣé iṣẹ Ọmọ Ogún ojú omi.
Ní ọdún 1971, o rin ìrin àjò kàn ṣùgbọ́n kò tó dé, Andrew tí kọnu ìfẹ sí Camilla, tó sí gbà láti fẹ̀ẹ́. Awọn ọrẹ́ rẹ̀ lòdì sí bí kò ṣe dúró de Charles, wọ́n ní kó rí ará rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Olórí Ọba.
Àwọn méjèèjì ní kádàrá kò fí wọ́n sílẹ̀, àárín àwọn alabarin kàn náà ní wọ́n jijọ n wà, kódà Charles ati Andrew Parker Bowles jọ má n ṣeré ìdárayá ‘Polo’ papọ̀ ní. Tọkọtaya náà ní kí Charles jẹ́ Bàbá ìsàlẹ̀ fún akọni àwọn, Tom, ti aworan ọjọ náà fi hàn pé ọrọ ẹfẹ lásán ni.
Ní ọdún 1981 siwaju ní Charles pàdé ọmọbìnrin míràn, tó sí kọnu ìfẹ sí Lady Diana Spencer. Ṣùgbọ́n Camilla kò kúrò nínú ayé rẹ̀.
Diana, nínú ìwé ìtàn tí Andrew Morton ṣé àkọsílẹ̀ rẹ̀, sọ pé bí Diana ṣé wọgile ìgbéyàwó wọn tó kù ọjọ́ méjì nítorí pé o ri Ẹ̀gbá ọwọ́ tí Charles fẹ́ fún Camilla tí wọ́n kọ “F” àti “G” si lara, orúkọ apejẹ tí àwọn méjèèjì fún ará wọ́n ní Fred àti Gladys.
Igbeyawo Camilla wa sí òpin lọ́dún 1995. Nigbati ìgbéyàwó Charles àti Diana náà kọlù ìgi lọ́dún 1996.
Ìfẹ tí Camilla ní sí Charles ló mú pinnu láti dúró tíì lai wò ọrọ kàn tó n já kiri àti pàápàá jùlọ, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Tom ati Laura.
Lọ́dún 2005, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, Harry, ẹní ọdún mọkanlelogun sọ pé Camilla jẹ́ “Obìnrin réré” tó mú inú Bàbá àwọn dùn.
Ojúṣe ipò Ọba jẹ́ adanikanṣe – Bi Charles sí ṣe n lọrá láti fí Camilla sílẹ̀ ló fihàn pé o ṣeéṣe kó tí mọ ṣáájú pé obìnrin náà nìkan ní ẹnìkán ṣoṣo tó lè jẹ́ alabarin tí òun nilo nínú ojúṣe ipò Ọba tí òun gbà.
BBC/Lekan Orenuga
Leave a Reply