Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ẹgbẹ́ Kàn Bú Ẹnu àtẹ Lù Bí Ìjọba Ìpínlè Nassarawa Ṣé Kọ̀ ìhà Aibikita Sí Ifeto-sọmọ-bibi

0 151

Àìní iṣeto owo Ìjọba Ìpínlè Nassarawa lo fa idiwọ lati kojú Ifeto-somo-bibi ni ipinlẹ naa.

Eyi ni Àjọ Pathfinder International tọka sí níbí ètò ti wọn ṣe pẹlú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ Asopọ Agbegbe fun Ilera ati Ikede Abẹ́lé Fun Ifeto-somo-bibi (Community Link For Health and Family Planning Advocacy “CLHFPA”) níbi àpérò ọlọ́jọ́ kan tí wọ́n ṣé pẹlú àwọn akọroyin lori Ifeto-somo-bibi ni ipinlẹ naa.

Olori Ẹgbẹ náà, Iyaafin Mary Ashenaye, sọ pe ọgbọn miliọnu naira N30m ti wọn ya sọ tọ fun eto náà ninu eto ìṣúná ipinlẹ náà tí 2022 ko tii gbà itusilẹ lati ṣe awọn òun tó tọ àti bi o ti yẹ ní ìpínlẹ̀ náà.

“Bí ètò ìṣúná fún Ifeto-sọmọ-bibi ṣe di ti ìdá-ìkẹhìn (Q4) ti ọdun ko bójú mú tó ní ẹka ìlera.”

Iyaafin Ashenaye tún bú ẹnu àtẹ lù ìwà aibikita ìjọ̀ba ipinlẹ náà làti nawo sí ètò Ifeto-sọmọ-bibi, tí a sì pinnu láti dènà ikú àwọn ìyá àti ọmọdé.

Bákan náà, Akọwe ẹgbẹ́ náà ní tirẹ̀, Ọgbẹni Kalu Idika gboriyin fún ìjọba ìpínlẹ̀ náà fún atunwo ètò ìṣúná náà láti mílíọ̀nù marun-un náírà (N5m) sí ọgbọn mílíọ̀nù náírà (N30m) lọ́dọọdún nínú ètò ìṣúná ọdún 2022, nígbà tó ṣakiyesi pé itusilẹ owó náà ní kiakia yóò yàrá mú ètò náà tó dáradára.

Ṣùgbọ́n aṣojú Kọmisana fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ náà àti alamojuto ètò Ifeto-sọmọ-bibi, Salomi Aya sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí n sá gbogbo àgbàrá rẹ láti ṣé àtìlẹ́yìn àti láti ṣe ètò tó múná dóko sílẹ ní Ìpínlẹ̀ náà.
O sọ pé agbawi àti àtìlẹ́yìn tí Pathfinder International, CLHFPA àti àwọn alabaṣiṣẹpọ mìíràn tí yọrí sí idinku ikú ìyá àti ọmọ ìkókó ní ìpínlẹ̀ náà.
O yìn àwọn oníròyìn fún ipá atí akitiyan wọn pẹ̀lú àwọn alabaṣiṣẹpọ mìíràn nípa wiwakọ Ifeto-sọmọ-bibi dé ibí tó lapẹẹrẹ.

Iyaafin Aya sọ pé àwọn aṣáájú ìbílẹ̀ àti ẹsìn, tí wọ́n kọti ko kan mi tẹlẹ tí f’ẹsẹ múlẹ ní báyíì.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.