Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà Fẹ́ Ètò tó Dára Fún Bọ́ọ̀lù Afẹsẹgba Ní ilẹ̀ Nàìjíríà

0 125

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà (ANFPU), tí pepe fún ṣíṣe ètò àti ìlànà tó dára jùlọ fún gbogbo ìpele tí bọ́ọ̀lù afẹsẹgba nti orílẹ-èdè náà.


Abdul Sule, Alàkóso tí ẹgbẹ́ náà sọ pé, liigi agbabuta gbogbo orílẹ-èdè ní o má n ṣé ìdàgbàsókè bọ́ọ̀lù afẹsẹgba.
Àgbàbọ́ọ̀lu tẹlẹ rí náà bú ẹnu àtẹ lù bí orílẹ-èdè yìí ṣé n pàdánù ọpọ ọjẹ wẹwẹ àgbàbọ́ọ̀lu tó yanranti laibikita nipa bí ipò liigi agbabuta (NPFL) orílẹ-èdè ti ṣé wà.

“NPFL nilo onigbọwọ ní kíákíá àti pé báwo ní yóò ṣé rí onigbọwọ, òún nipé kí a ṣé ètò fún òun gbogbo ti a nilo fún.

“Òun pàtàkì jùlọ ní igbekalẹ ètò to yanranti tí yóò sì bẹrẹ láti ipinlẹ, a sì gbọdọ̀ ní ilé ìgbà-bọ́ọ̀lù tó dára àti isànwò tó dára fún áwọn àgbàbọ́ọ̀lu àti awọn eleto bíi afọn-feèrè.”

“O sọ pé ẹgbẹ́ náà yóò ṣiṣẹ́ ni pẹkipẹki pẹlú àwọn ẹgbẹ́ àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso liigi (LMC) láti ríi dájú pé ètò tó dára jùlọ àti ìrànlọ́wọ́ wà fún àwọn agbàbọ́ọ̀lù.”

Agbàbọ́ọ̀lù tẹlẹ rí ní ìkọ Stationaries Stores FC ní ìrètí pé tí ètò tòótọ ba wà, dídùn lọsan yóò so, tí liigi Nàìjíríà yóò wá láàrin àwọn tó dára jùlọ ni ilẹ̀ Adúláwọ̀.

“Ẹgbẹ́ náà tí ṣé ètò ọpọlọpọ àwọn idanilẹkọ fún agbàbọ́ọ̀lù Nàìjíríà tẹlẹ àti tí n gbà bọ́ọ̀lù lọwọ làti mọ̀ àgbàrá wọ́n àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nilo.”

“O wà kesi àwọn tí wọ́n n wa ipò làti di olórí igbimo ẹgbẹ agbàbọ́ọ̀lu Nàìjíríà (NFF) láti ṣé agbekalẹ àwọn ìlànà tí yóò yàrá mú ìdàgbàsókè bá bọ́ọ̀lù Nàìjíríà.”

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.