Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Petroleum and Natural Gas Senior Staff ti Nàìjíríà, PENGASSAN ti halẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìdásẹsílẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí latari àpọ̀jù olè jija ati ibankanje ti epo robi ti orilẹ-ede yìí.
Ààrẹ PENGASSAN ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Festus Osifo ló sọ èyi di mímọ̀ ní ìpàdé àpérò kan tó wáyé ní Àbújá, olú ìlú Nàìjíríà.
Ọ̀gbẹ́ni Osifo kẹ́dùn pé olè epo rọ̀bì ti ba ètò ọrọ̀ ajé o orílẹ̀-èdè yìí jẹ. O tẹnumọ pé àwọn òsìsẹ́ epo rọ̀bì sì ti setán láti yan isẹ́ wọn lódì tí ìjọba Nàìjíríà bá kùnà láti se ohun tí wọ́n ń bèèrè fún láti gbógun ti olè epo àti bíba nǹkan rẹ̀ jẹ́.
Osifo sọ pé ó se òun ní kàyéfì ìdí rẹ̀ tí ìjọba kò fi lè gbé ìmọ̀-ẹ̀rọ gíga kalẹ̀ láti kojú àwọn ewu náà.
Ó tún yọọwí pé ẹgbẹ́ ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìdasẹ́sílẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí láti tẹ́ àwọn ìbéèrè wọn sílẹ̀ fún ìjọba.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply