Ilé-iṣẹ́ Ìjọba tó mójútó ìròyìn, àṣà àti ìṣe, tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pèlú olùgbọ̀wọ́ àjọ àfihàn aṣa ati iṣẹ ni àgbáyé, ti bèrè ètò àfihàn aṣa àti iṣẹ ni ọjọ́ Isẹgun, ọjọ kàrún, yóò sì parí ní ọjọ́ kẹtala oṣù kẹsán ọdún 2022 ni gbọgán Amphi Cyprus, Ekuwens cultural center ni ìlú Abuja.
Ètò yìí wà fún gbígbé àṣà àti iṣẹ́ wa lárugẹ àti àfihàn àwọn èwà iṣẹ wa, pẹ̀lú láti ri ẹbùn ọpọlọ ti àwọn ọ̀dọ́ wa ní
Bákan náà wọn, yóò ṣe àfihàn iṣẹ àwọn àládani pèlú, ẹni tí iṣẹ rẹ bá dára jùlọ yóò gbà ẹ̀bùn
Níbi ìpàtẹ àṣà àti ìṣe elekeji tó n lọ lọ́wọ́ nílu Abuja, ọ̀gbẹ́ni Femi Coker sọ̀rọ̀ lori pàtàkì àti anfaani eto ohun lati mu igberu ba eto ọrọ ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni eyi ti o rọ ìjọba láti gbaruku ti ÀṢÀ àti iṣẹ́ torípé o nii se pẹlú ìrírí, ihuwasi ti o n pese ise fun awon eniyan yato si ona epo robi àti eto ọgbin nìkan.