Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí ń darí ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 211

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí, ń darí ìpàdé Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ní gbọ̀ngàn Ìgbìmọ̀,láyìíká ọ́f́íisì ààrẹ,ní  Víllà,ní ìlú Àbújá.

Ipade naa to bẹrẹ ni agogo mẹsan an owurọ ni Igbakeji Aarẹ Yẹmi Ọṣinbajo, Akọwe fun ijoba apapo, Boss Mustapha,Ọga agba awọn Oṣiṣẹ  Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ati Ọga agba fun awọn oṣiṣẹ ijọba apaapọ, Dokita Fọlashade Yẹmi Ẹsan wa nibẹ.

 

Awọn minisita ti o tun wa nijoko nibi ipade naa ni: Dokita Zainab Ahmed (inawo), Hadi Sirika (ọkọ Ofurufu), Dokita Osagie Ehanire (ilera), Adamu Adamu (Ẹkọ), Dokita Geoffrey Onyema (Ọrọ okeere), Lai Mohammed (ibaraẹnisọrọ) ati Niyi Adebayo ( Ile-iṣẹ, Iṣowo ati Idoko-owo).

Awọn minisita  Ipinlẹ fun Ayika, Sharon Ikeazor ati ọrọ okeere, Zubairu Dada ati Alakoso Iṣowo, Doyin Salami tun wa nibẹ pẹlu.

Awọn minisita miiran n kopa  lati awọn ọfiisi wọn kaakiri ni Abuja.

Alaye lẹkunrẹrẹ nigbamii…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button