Àjọ tó n gbógun ti iwa ibajẹ àti ṣíṣe owó ìlú kumo-kumo, EFCC ti gba Adepoju Olawale Sunday to ni ilé ijo kan ni agbègbè Ring Road ni ìlú ìbàdàn mú.
Ajo EFCC, ẹkùn tí ìlú ìbàdàn tí ì ṣe olu ìlú ìpínlè Òyó ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà lo mú arákùnrin Adepoju Olawale Sunday pẹlu àwọn afurasi mokanlelogun míràn nipasẹ iṣẹ ìwádìí tó ṣe àfihàn onírúurú iṣẹ jibiti tí wọn n ṣe.
Lara àwọn afurasi onijibiti orí ẹrọ ayélujára tí EFCC gba mu ni tọkọtaya kan, Aladenusi Adegboyega Ayodeji àti Aladenusi Omowunmi Sadiat, tí àdàpè oruka awọn méjèèjì a máa jẹ (Bonnie and Clyde).
Bákan náà ni àjọ ohun tún mú arákùnrin akẹkọ-gboye ilé ẹkọ gíga fasiti Olabisi Onabanjo, ni ìpínlè Ògùn, ẹni ọdún merindinlogbon (36), ti o ni ilé iṣẹ Special Service Global Trust (S.S.G), pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ 2020 Range Rover.
Awọn ohun tí EFCC ka mo awon afurasi náà lowo ni ọkọ ayọkẹlẹ marun (5), ẹrọ agbeletan alatagba, ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati awọn ìwé miran ti won fi n lu Jibiti.
Gẹgẹ bí adari ẹka ìròyìn ati ipolongo àjọ EFCC, Wilson Uwajure ṣe sàlàyé, àwọn afurasi onijibiti náà ni yóò fi ojú ba ilé ẹjọ ni kété ti iṣẹ ìwádìí ba ti parí.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply