Take a fresh look at your lifestyle.

Jonathan, Tinúbu, Àti Àwọn Míràn Wá Síbi Ayẹyẹ Ọjọ-Ìbi Kukah

0 289

 

Ààrẹ Orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ ri, Goodluck Jonathan, Tinúbú àti àwọn àgba Orilẹ̀ ẹdè yìí míràn, wá síbi ayẹyẹ ọjọ ìbi Bísọ́ọ̀bù Ìjo Kátólìkì ti Sókótó Diocese, Bishop Matthew Kukah ẹni Àádọ̀rin ọdún, ní Àbújá ní ọjọ́ Ọjọ́rú.

Àwọn olùdárí náà sọ̀rọ̀ níbi oúnjẹ alẹ́ àpèjẹ láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí Àádọ̀rin ọdún ti Alàgbà Kukah.

Gẹ́gẹ́ bí Jonathan ṣe sọ, Kukah jẹ́ àlùfáà tí ó fẹ́ àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ti orile ede Nàìjíríà; ti o le se ohunkohun lati rii pe iṣọkan ati idajọ ododo wa lorile ede yii. O bawon so ooto oro nigba to ri wipe won ko se daadaa to lori alefa botiwu ki won je ọ̀rẹ́ to.

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sọ pé lati ara awọn irin-ajo ati àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti oun ti se kakiri, oun rii pe awọn iriri ati awọn ìgbìyànjú fún ìdàgbàsókè jẹ iru kanna ni ọpọlọpọ orile ede to wa ni ile adúláwò.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, Nàìjíríà le ma ti wa nibiti gbogbo eniyan fẹ ki o wa, ṣugbọn ko yẹ ki gbogbo eniyan juwọ sile tabi sọ ireti nu nipa wiwo aisedede wa nikan.

Ààrẹ tẹlẹri fi ayọ̀ hàn pé àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ń kópa takuntakun nínú òṣèlú ọdún 2023 tó ń bọ.

Ó ṣe àkíyèsí pé gẹ́gẹ́ bí ìsirò tuntun láti ọ̀dọ̀ àjọ INEC, áwọn ọ̀dọ́ ni ó pọ̀ jùlọ nínu àwọn olùdìbò tó dín díẹ̀ ní ọgọ́rùn ún Mílíọ̀nù tó forúko sílẹ̀. O fi kun pé àpeere rere lèyí j̀ẹ́ láti yan àwọn ènìyàn rere tí yóò mú orílẹ̀ èdè wa lọ sí ilẹ̀ ìlérí.

 

 

Tèmìtọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button