Gómìnà Yóbè fọwọ́ sí ìgbanisíṣẹ́ àwọn Òṣìṣẹ́ Ìlera mẹ́rìnlé-láàdóje
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba ìpínlẹ̀ Yóbè ní ọjọ́ Àìkú, fọwọ́sí ìgbani síṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera mẹ́rìnlé-láàdóje láti mú ìrọ̀rùn bá iṣẹ́ ìlera ní ìpínlẹ̀ náà.
Gomina Mai Mala Buni sọ eyi ninu ọrọ kan nipasẹ Oludari Gbogbogboo eto ibaraẹnisọrọ ati Awọn ọrọ awọn oniroyin, Alhaji Mamman Mohammed ni Damaturu,o sọ pe awọn oṣiṣẹ naa ti pari ni ile-iwe giga olugbẹbi ati olutọju[nọọsi] ti Shehu Sule , Damaturu.
Awọn oṣiṣẹ naa jẹ agbẹbi mẹtadin-laadọrin,Nọọsi mejila,ati awọn Nọọsi abẹle marunle-laadọta.
Gomina tun fọwọsi fifun awọn ọmọ ile-iwe nọọsi mẹtadin-laadọsan naa ni iye owo ẹgbẹrun mẹwaa Naira loṣooṣu fun ẹni kọọkan.
Leave a Reply