Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó Se Ìlérí Láti Kojú Àwọn Ìpèníjà Tí Àwọn Onìpinlẹ̀ṣẹ̀ Ń Dojúkọ̀ Lórí Ètò Iṣẹ́́-Ọ̀gbìn

0 99

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ìlú Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Babájídé Sanwó-Olú, ti ṣe ìlérí láti kọjú àwọn ìpèníjà tí àwọn Onìpinlẹ̀ṣẹ̀ ètò iṣẹ-ọ̀gbìn ń dojú kọ lórílẹ̀, ó tún sèlérí fífún àwọn ènìyàn ní ìrètí nípasẹ̀ ìlọsíwájú ìgbésí ayé tó dára.

Sanwó-Olú sọ èyí lákókò ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ti àwọn ètò oúnje yanturu àti ibùdo ohun èlò ti “Lagos Central food security systems and logistics hub” ni Ketu-Ereyun Ẹ̀pẹ́.
Gómìnà, ti o ni inúdídún si ibẹrẹ iṣẹ rere naa, ṣe àpèjúwe ètò náà gẹ́gẹ́bí ohun máleegbàgbé ninu itan orile ede Naijiria lọ sí èbúté ògo nípasẹ̀ eto ounje bọ̀lúyó.

Sanwo-Olu sọ pe iṣẹ akanṣe naa yoo jẹ imuse ni awọn ipele meji, yoo pese ọrọ fun eniyan to le ni mílíọ̀nù màrún, yóò bọ́ olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó tólé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá, oúnjẹ fún bí osù mẹ́ta, yóò pèsè awọn ohun elo ipamọ fun awọn oko nla ju to ju bii 1,500 fun ọjọ kan lo, yoo ṣiṣe iwulo fun ẹgbẹẹgbẹ̀rún awọn òsìṣẹ́ ní ọdọọdún, ati wipe yoo ṣilekun awọn okowo nla sile. O ni ireti pe iṣẹ àkànṣe náà yóò bí ọ̀pọ̀ yanturu, àti èrè ńlá tabua fún àwọn àgbẹ̀ àti àwọn míràn.
Komísánà fún ètò-ọ̀gbìn, Abísọ́lá Olúsànyà, nítirẹ̀ sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ tilọ láti ṣètò iṣẹ́ àkànṣe yìí, èyí tí ó tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ìpalẹ̀mọ́ ogun rere míràn ti ìjọba Babájídé Olúsọlá Sanwó-Olú tún fi lọ́lẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.