Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Bauchi, Malam Isa Yuguda sọ pé Bọ́lá Tinubu yóò kojú ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ dáradára tí wọ́n bá yan òun gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Yuguda ti o sọ eyi ni Ọjọ Aje,o gbagbọ pe gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) tẹlẹ, o ri iwa ibajẹẹ gbankọgbi lakoko iṣejọba ọdun mẹrindin-logun ẹgbẹ naa, eyi ti o iṣakoso yi jogun lọwọ wọn.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu wi pe o kuna ninu ileri re lati gbogun ti iwa jegudujera pelu bi o ti n gbiyanju gbogbo agbara rẹ.
Nigba to n soro siwaju, Yuguda to je oloye agba fun ẹgbẹ APC, sọ pe o da oun loju wi pe ti Tinubu ba di olori orile-ede,yoo gbe igbesẹ lori iṣoro iwa ibajẹ.
Leave a Reply