Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ PDP Ṣàpèjúwe Ààrẹ Nàìjíríà Tẹlẹri Gẹ́gẹ́ Bí Aṣáájú Onígboyà

0 425

Ẹgbẹ́ People’s Democratic Party, PDP, ṣàpèjúwe ààrẹ ológun Nàìjiríà tẹ́lẹ̀rí, General Ibrahim Babangida gẹ́gẹ́ bí adarí onígboyà, àti olùfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ tí ó dúró sinsin àti olùfarajì sí ìsòkan orílẹ̀-èdè, ìdúróṣinṣin, àti ìdàgbàsokè ètò-ọrọ̀ ajé rẹ̀.

 

Akọ̀wé lórí ètò ìkéde fún ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Débọ̀ Ológunàgbà, nínú ọrọ kan to fi ki Babangida ku ayeye ojo ibi odun kokanlelogorin (81), o so wipe o je eni ti ko dinku ninu sísájú àwọn ohun ìdàgb̀asókè ti ìjoba rẹ̀ fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún àwọn ohun èlò àti ìdàgbàsókè ètò ìmúlò ní àwọn ipa pàtàkì ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíŕià.

 

Ó fi kún un pé ẹgbẹ́ òsèlú PDP ń se ayẹyẹ àyájọ́ General Ibrahim Babangida lásìkò ayọ̀ yìí, tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, nínú àánú R̀e, kí ó túbọ̀ fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ìlera kí orílẹ̀ èdè wa lè tẹ̀síwájú láti jẹ ànfààní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí àti ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀. Pááp̀áa ńinú iṣẹ́ àpínfúnni ti Ẹgbẹ́ PDP láti gbàlà, se àtúnse àti láti tún orílẹ̀ èdè wa kọ́.

A bí General Ibrahim Badamasi Babangida ní ọjọ́ kẹtà dín lógún, osù kẹ́jọ  ọdun 1941; Ó sìn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ológun ti Nàìjíríà láti ọdún 1985 sí 1993.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button