Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Kẹ́nyà Ti Wọ́n Sẹ̀sẹ̀ Dìbò Yàn Àti Alátakò Rẹ̀ Yóò Jùmọ̀ Pàdé Sẹ́nátọ̀ Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà

0 276

Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Kẹ́nyà tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ dìbò yàn láìpẹ́ yìí àti alátakò rẹ̀, Raila Odinga yóò jùmọ̀ pàdé Sẹ́nétọ̀ Chris Coon ti Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nínú àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ márùn ún rẹ̀ sí ilẹ̀ Adúláwò.

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ko tii ki Ọ̀gbẹ́ni Ruto ku oríire láti ìgbàtí wọ́n ti se ìkéde re pe o ja ewé olúborí bẹ́ẹ̀ náà ni Ọ̀gbẹ́ni Odinga  naa sọ pe oun kọ àbájàde èsì ìbò náà.

Sẹ́nátọ̀ Coon ati awọn ẹmẹ̀wà rẹ yóò tun pade pẹlu Aare Uhuru Kenyatta. Yóò de si Ìlu Nairobi ni ale ojo ojoru, yoo se ipade po pelu awon olori mẹ́tẹ̀ẹ̀ta

lórí ìlera, ààbò, àti ètò ọrọ̀ ajé.

Àwọn Aṣojú náà yóò tún pàdé àwọn alábójútó, àwọn olùpèsè ìlera, àti àwọn àjọ tí n ṣiṣẹ́ láti ró àwọn ọmọbìrin  lágbára.

 

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button