Take a fresh look at your lifestyle.

Áà! Ìsẹ̀lẹ̀ Omíyalé Pa Ènìyàn Mẹ́ẹ̀dógún Ní Agbègbè Ìwọ̀-Oòrùn China

0 133

Ìsẹ̀lẹ̀ Omíyalé àgbàrá yaa sọ́ọ́bù tí ó ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ òjò àir̀ọ̀dá ńlá ní agbègbè ìwọ̀-oòrùn ti Qinghai ti Ìlú China ti gba ẹ̀mín ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún, tí ènìyàn mẹ́rin dín lógójì sì di àwátì.

Ìròyìn sọ pé òjò ńlá tó lágbára bẹ̀rẹ̀ lójijì ní agbègbè Datong Hui àti Tu Autonomous County ti agbègbè Qinghai, ní alẹ́ ọjọ́ Ọjọ́rú, tí ó sì fa ìkún omi ní àwọn orí òkè àti ilẹ̀ ríri. Àwọn odò tí ó ń sàn yà bàrá kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n sì fi opópónà abúlé àti ìletò se ọ̀nà wọn tí ó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ omíyalé, àgbàrá yà ìgboro lọ́jọ́ burúkú èsù gbomimu náà.

Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé Nigba ni ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún yọ lẹ́nu, Ìjọba ìbílẹ̀ sì ti rán àwọn adólà ẹ̀mí bíi Ẹgbẹ̀rún méjì síta, pẹ̀lú ọkọ̀ tó súnmọ́ igba láti gba ẹ̀mín àwọn ènìyàn là.
Láti Oṣù Kàrún ní orílẹ̀ èdè China ti ń ní ìdojúko pẹ̀lu ojú ọjọ́ tó gbóná janjan àti ìkún omi tó lágbára, Ìjọba wọn ti sọ pé ó ti di dandan kí eléyìí ní ipa lórí ètò-ọrọ̀ ajé àti àwùjọ wọn.

 

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.