Take a fresh look at your lifestyle.

Olu-ilu: Ọwọ́ pálába àwọn afurasí ségi

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 58

Ọwọ́ Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ètò olú-ìlú,FCTA,ti tẹ Àwọn Afurasí márùn ún kan tí wọ́n ń tà àti lo òògùn olóró Lábẹ́ afárá ní Wusé,ní ìlú Àbújá.

Igbesẹ yii jẹ apakan eto lati palẹmọ awọn ile ti ko bofin mu ti o n lọ lọwọ  laarin olu-ilu, lorilẹ-ede.

Awọn ọdaràn fẹsẹ fẹẹ nigbati wọn ri apapọ ẹgbẹ Minisita olu-ilu, ṣugbọn ọwọ awọn oṣiṣẹ aabo tẹ marun ninu awọn afurasi ọdaràn naa pẹlu oogun oloro.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Oluranlọwọ agba pataki fun minisita olu-ilu lori eto abojuto, ayẹwo ati imuṣẹ, Ọgbẹni Ikharo Attah, nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ,bẹnu atẹ lu ilo aitọ ti wọn n lo afara naa, paapaa julo bi awon ti n ta ounjẹ  ati awọn to n gbe nibẹ ṣe ba afara naa jẹ, eyi ti o le fa ewu fun awọn  olugbe.

Leave A Reply

Your email address will not be published.