Take a fresh look at your lifestyle.

CAF Yan Lamin Bajo orílẹ̀-èdè Gámúbíà gẹ́gẹ́ bí ààrẹ WAFU A

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 1,475

Wọ́n ti yan Olórí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Gámúbíà (GFF), Lamin Kabba Bajo, gẹ́gẹ́ bíí Ààrẹ tuntun fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Iwò-oòrùn Áfíríkà (WAFU) agbègbè A.

Wọn yan Bajo lakoko Apejọ Gbogbogboo agbegbe ni Arusha,lorilẹ-ede Tanzania.Wọn dibo yan an laini olabadu lakoko ipade nibiti CAF ti n ṣe apejọ  Gbogbogboo ẹlẹẹkẹrinle-logoji rẹ.Yoo ṣiṣẹ fun ọdun meji ni ọfiisi  awọn ọmọ ẹgbẹ agbegbe mẹsan.

Aarẹ CAF, Dokita Patrice Motsepe wa nibi ipade  WAFU agbegbe A, Apejọ Gbogbogboo gẹgẹ bi apakan  Ọjọ ayajọ Awọn Agbegbe lakoko ipade ọlọjọ mẹta ni Tanzania. Dokita Motsepe tun fidi ifọkansi rẹ mulẹ lati mu ayipada to dara ba  bọọlu afẹsẹgba Afirika  pẹlu igbero awọn iṣẹ akanṣe bọọlu.

Leave A Reply

Your email address will not be published.