Asòfin ṣàpéjúwe ìyanṣélódì ẹgbẹ́ olùkọ́ni fáfítì gẹ́gẹ́ bí ìtìjú fórílẹ̀-èdè
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọmọ ẹgbẹ́ Aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Hon Bùsáyọ̀ Olúwọlé Ọ̀ké ti ṣàpéjúwe ìdaṣẹ́sílẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga orílẹ̀-èdè lábẹ́ agbòòrùn (ASUU), gẹ́gẹ́ bí ìtìjú fún orílẹ̀-èdè.
Ninu atẹjade kan ti aṣofin naa fi sita nilu Abuja, o ni wahala to waye laarin ASUU ati Ijọba apapọ to mu ki wọn ti awọn ile iwe giga orilẹ-ede pa fun ọpọlọpọ oṣu sẹyin, ti ko si lojutu yẹ ki o jẹ nkan ti yoo jẹ gbogbo eniyan logun
Aṣofin naa wa da laba pe ki Ile-igbimọ Aṣofin Orilẹ-ede ti o lọ fun isinmi ọdọọdun lọwọlọwọ bayii, yẹ ki o tun ṣe apejọ lẹsẹkẹsẹ lati pari idaṣẹsilẹ naa laisi idaduro kankan.
Leave a Reply