Take a fresh look at your lifestyle.

Ese Brume gba àmì ẹ̀yẹ Góòlù Nínú eré Ìfò fífò Àwọn Obìnrin

0 225

Ní ọjọ́ tí o kẹhin eré ìdárayá ní àjọ Commonwealth ní Birmingham, ọdún 2022, eléré ìdárayá Nàìjíríà Ese Brume fo rekọọdu tuntun lẹẹmeji, 7.00m (+1.6) èyí sì mu gba àkọlé oní Ìyẹ̀pẹ̀ fífò àjọ Commonwealth ti o ti gba sẹhin ni ẹda Glasgow 2014.

Ní àkókò yíì, o ti kọlu 7m lẹmeji, o fo 7.02m láti parí pẹ̀lú ipò Kejì ní Ìdíje eré-ìdárayá Àgbáyé ní Eugene. Pẹ̀lú iṣẹgun rẹ̀ ní Birmingham, ó ti di obìnrin Áfíríkà àkọ́kọ́ nínú ìtàn láti fo àwọn ààmì òfin mẹrin ju 7m lọ.

Brume ti gba àkọlé ife ẹ̀yẹ àjọ Commonwealth méjì báyìí, àmì ẹ̀yẹ fàdákà Olympic kan, àmì ẹ̀yẹ méjì níbi ìdíje eré ìdárayá àgbáyé (Idẹ & Fàdákà), àti àwọn àkọlé ilẹ̀ Áfíríkà lọpọlọpọ.

 

Ọláyinká Akíntọ́lá.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button