Ààrẹ Muhammadu Buhari, gbósùbà fún àwọn eléré ìdárayá tó lọ se aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú ìdíje àjọ Commonwealth, Birmingham 2022, ti wọn sì fakọyo ní ọjọ́ Àìkú.
Ààrẹ yin àwọn aṣojú mẹrinlelaadorun tí wọ́n ṣe aṣojú rere, ti wọn si gbe àsìá Nàìjíríà ní àwọn eré ìdárayá mẹsan, Ààrẹ ki wọn ku oríire nipa gbigba àwọn àmì ẹ̀yẹ àgbáyé àti ti àjọ commonwealth, mí mú orí orílẹ-èdè ati ilẹ̀ Áfíríkà wú.
Pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ marun-din-logoji ti wọn gbà lapapọ to pín sí ìsòrí mẹta, àmì ẹ̀yẹ góòlù méjìlá, fadaka mẹsan àti idẹ Mẹrinla, àti àwọn àmì-ẹ̀rí díẹ síi tí wọn gbà fún orílẹ-èdè ní ọjọ́ tí eré àjọ commonwealth pari. Ààrẹ dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ìràwọ̀ dídán orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó bá àwọn eléré ti o dára jùlọ ní àgbáyé sáré.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply