Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Olùpèsè Àlááfíà UN dàbọn bolẹ̀ Ní DR Congo,tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sí farapa

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 365

Àwọn ọmọ ogun àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN tí ń pèsè àláfíà tí ń padà wọṣẹ́ lẹ́yìn ìsinmi sí Democratic Republic of Congo dàbọn bolẹ̀ ní ibùdó ààlà kan,tí wọ́n sì ṣekú pa ènìyàn méjì, tí ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún míràn sì  farapa.

Ijọba Congo ati awọn ọmọ ogun UN ti n pese aabo alafia sọ eyi ni ọjọ Aiku.

Iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ Aiku, ni agbegbe Beni ti DRC, bi awọn ọmọ ogun MONUSCO’s to n pese alaafia  ti kọja si orilẹ-ede lati Uganda.

Akowe Gbogbogbo UN Antonio Guterres sọ pe iroyin iku naa  bi oun “binu”, o si jẹ “ibanujẹ ati iyalẹnu” . O beere “ẹkunrẹrẹ alaye,” atẹjade kan lati UN ọdọ.

Awọn fidio ti wọn pin lori ayelujara awujọ isẹlẹ naa fihan pe ọkunrin kan ninu aṣọ ọlọpa ati omiiran ninu aṣọ ologun  n lọ si ibi ti awọn ọkọ abanirin  UN to wa loju kan lẹyin ọna ti wọn ti di pa ni ilu Kasindi.

Lẹyin ti wọ jọ sọrọ, awọn olupese alafia UN dabọn bolẹ ti  ẹnu-bode naa si ṣii, ti o si n yinbọn bo ṣe n wakọ lọ. Awọn ti n woran  tuka ti awọn miran si farapamọ.

Aṣoju fun gomina North Kivu ni Kasindi, Barthelemy Kambale Siva, sọ pe eniyan mẹjọ, pẹlu awọn ọlọpa meji, ni o farapa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button