Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Uganda ti fi ẹ̀hónú wọn hàn bí ìgbé ayé ṣe nira fún wọn,wọ́n gbégi dí àwọn òpópónà ní ilà-oòrùn ìgboro Jinja, ibùdó pàtàkì kan ní òpópónà ààlà orílẹ̀-èdè náà pẹ́lù Kẹ́níyà.
Ifehonu han yii waye lọjọ keji ti awọn alaṣẹ orilẹ-ede Ila-oorun Afirika kilọ nipa ẹsun iditẹ kan lati ọdọ diẹ ninu awọn “to wa lorilẹ-ede ati ni okeere” lati gba awọn eniyan niyanju lati wa ninu ile fun ọjọ mẹta fun fifi ẹhonu wọn han fun bi gbogbo nnkan ṣe gbowolori ti eleyi fa dindinku iye nnkan owo ṣilinsi Uganda le ra.
Ọlọpaa gbiyanju lati yọ awọn taya ti wọn sun nina kuro ni arin opopona, gẹgẹ bi awọn fọto ti o jade ninu iwe iroyin agbegbe, Daily Monitor.
Awọn alaṣẹ orilẹ-ede Uganda gbe gbogbo ẹbi ọwọn gogo naa lori ogun to n waye ni Ukireini.
Leave a Reply