Take a fresh look at your lifestyle.

UCH Fagilé ìgbésẹ̀ gbígba ẹgbẹ̀rún kan Náírà owó-iná Lọ́wọ́ Àwọn Aláìsàn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 321

Àwọn alákòóso ilé-ìwòsàn ilé-ẹ̀kọ́ gíga fáfitì (UCH) Ìbàdàn, sọ pé wọ́n ti fagilé ìpinnu wọn tẹ́lẹ̀ láti fi ẹgbẹ̀rún kan Náírà owó iná mọ̀nàmọ́ná kún iye  tí gbogbo aláìsàn tí wọ́n bá gbà wọlé ní ilé ìwòsàn náà máa san.

Agbẹnusọ fun ile-iwosan naa, Ọgbẹni Toye Akinrinlọla,ni o sọ ọrọ naa ni ilu Ibadan nigba to n ṣakọrọ ọrọ adari eto iṣakoso ile-ewosan naa, Ọgbẹni Stephen Ọladejo,o sọ pe ko si igba kan ti ile-iwosan naa n gba iru owo bẹẹ, nitori pe eto ilera ọmọ Naijiria to peye lo jẹ wọn logun.

O sọ pe iwe-adehun ti wọn n tọka si jẹ akọsilẹ inu-ile, eyiti wọn ko mulo lẹyin atunyẹwo kikun lori awọn ilana inu-ile fun iru awọn ọran bẹẹ ati pe wọn ti fagile lati igba naa. O ni ko si igba kankan ti ile-iwosan naa gba owo ina mọnamọna lọwọ alaisan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button