Take a fresh look at your lifestyle.

TSO fòhùntẹ̀ lu Nasir El-Rufai gẹ́gẹ́ bí igbákejì

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 82

Ẹgbẹ́ kan tó ń ṣàtìlẹyìn fún Asiwájú Tinubu (TSO), ti fọwọ́ sí yíyan Gómìnà ìpínlẹ̀ Kàdúná, Nasir El-Rufai, gẹ́gẹ́ bí igbákejì olùdíje  ipò Ààrẹ fún ẹgbẹ́ All Progressive Congress, APC, Bọ́lá Ahmed Tinubu.

Nigbati o nsọrọ lakoko apero iroyin kan ni Ọjọ Aje ni Kaduna, Alakoso Agba TSO, Aminu Suleiman, sọ pe ẹgbẹ fẹnu ko lori  yiyan El-Rufai lẹyin ipade pẹlu awọn  to ṣe pataki ninu ẹgbẹ lati agbegbe ariwa iwọ-oorun ati awọn toku.

Wọn gbagbọ pe yiyan igbakeji oludije yii yoo jẹ ifọsiwẹwẹ aṣeyọri pataki fun Tinubu lati jawe olubori ni 2023; nitori naa, ajo naa, ti o ti ṣe ayẹwo gbogbo awọn aṣayan, fẹ ki oludije APC fun igbakeji Aarẹ wa lati ariwa iwọ-oorun, eyiti o jẹ abala idibo ti o tobi julọ ni orilẹ-ede.

El-Rufai, ẹgbẹ naa fi kun un pe,o jẹ eniyan ti o ni iriri pupọ ti o ṣe daadaa ninu iṣelu ati iṣejọba ni ipele ijọba apapọ ati ti ipinlẹ ati pe o jẹ oludije to dara julọ lati kún Tinubu gẹgẹ bi Igbakeji Aarẹ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.