Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari dúpẹ́ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè Portugal fún gbígbà àwọn ọmọ Nàìjíríà tó tẹ̀dó sí Ukraine lálejò 

0 80

Ààrẹ Muhammadu Buhari pàdé Fernando Medina, Mayor ti ìlú Lisbon àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìlú ní ọjọ́ Jímọ̀, ó ṣe àfihàn ọpẹ́ àti ìmore rẹ̀ fún gbígba àwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá jùlọ àwọn tó sá fún ogun Ukraine.

Ààrẹ tún lo ayeye náà láti kí Mayor àti ẹgbẹ́ rẹẹ̀ kú oríre ìsẹ́gun ìbò wọn àti bí wọ́n ṣe jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bii Mayor ti ìlú Lisbon.

Mayor náà, lákòókò tí ó ń fún Ààrẹ Buhari ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìlú Lisbon, tẹnumọ́ àwọn ìbátan àṣà, itàn-àkọọ́lẹ̀, òṣèlú àti ti ìjọba ìlú Lisbon àti Abuja, tí ó ṣàlàyé àwọn kọ́kọ́rọ́ yìí bíi “àmì ìbọ̀wọ̀ àti ìmọrírì.”

 

Ọláyinká Akíntọ́lá.

Leave A Reply

Your email address will not be published.